← Àwon ètò
Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú II. Kro 20:22

Ohun Tí Baba Sọ
Ọjọ́ Mẹ́ta
Àwọn èrò ìfẹ́ tí Bàbá ní sí ọ pọ̀ ju iyanrìn etí òkun lọ. Ọmọ Rẹ̀ Olùfèẹ́ ni ọ́, inú Rẹ̀ sì dùn sí ọ! Ètò ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí jẹ́ ìpé fún ọ láti mọ àbúdà ẹni pípé àti ẹni àgbààyanu tí Bàbá rẹ ọ̀run jẹ́. Nínú ìfẹ́ Rẹ̀, kò sí ìlàkàkà tàbí ìbẹ̀rù, nítorí pé o wà ní àtẹ́lẹwọ́ Rẹ̀.

ÀDÌTÚ ORIN ÌYÌN
7 Awọn ọjọ
Àwọn ohun ìjinlẹ ti Ìyin: Nínú ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ méje yìí, Dúnsìn Oyèkan ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àdìtú inú orin ìyìn gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà àwọn onígbàgbọ́. Bi o ṣe kàá, ìwé májẹ̀mú Láíláí àti Májẹ̀mú Titun sì yànnànáa rẹ̀. Gbìyànjú láti lo àwọn oun ìjà ti ẹ̀míi nì, ní àkókò ayọ ju àkókò ìpèníjà lọ.