YouVersion Logo
Search Icon

ÌWÉ ÒWE 1

1
Anfaani Àwọn Òwe
1Àwọn òwe tí Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli pa, #1A. Ọba 4:32
2kí àwọn eniyan lè ní ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́,
kí òye ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ lè yé wọn,
3láti gba ẹ̀kọ́, tí yóo kọ́ni lọ́gbọ́n,
òdodo, ẹ̀tọ́ ati àìṣojúṣàájú,
4láti kọ́ onírẹ̀lẹ̀ lọ́gbọ́n,
kí á sì fi ìmọ̀ ati làákàyè fún ọ̀dọ́,
5kí ọlọ́gbọ́n lè gbọ́, kí ó sì fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀,
kí ẹni tí ó ní òye lè ní ìmọ̀ pẹlu.
6Láti lè mọ òwe ati àkàwé ọ̀rọ̀,
ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ati àdììtú ọ̀rọ̀.
Ìmọ̀ràn fún Àwọn Ọ̀dọ́
7Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀,
ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa pẹ̀gàn ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́. #Job 28:28; O. Daf 111:10; Owe 9:10; Sir 1:4
8Ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ẹ̀kọ́ baba rẹ,
má sì kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ,
9nítorí pé ẹ̀kọ́ tí wọn bá kọ́ ọ yóo dàbí adé tí ó lẹ́wà lórí rẹ,
ati bí ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ.
10Ìwọ ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́,
o ò gbọdọ̀ gbà.
11Bí wọn bá wí pé,
“Tẹ̀lé wa ká lọ,
kí á lọ sápamọ́ láti paniyan,
kí á lúgọ de aláìṣẹ̀,
12jẹ́ kí á gbé wọn mì láàyè
kí á gbé wọn mì lódidi bí isà òkú,
13a óo rí àwọn nǹkan olówó iyebíye kó,
ilé wa yóo sì kún fún ìkógun.
14Ìwọ ṣá darapọ̀ mọ́ wa,
kí á sì jọ lẹ̀dí àpò pọ̀.”
15Ọmọ mi, má bá wọn kẹ́gbẹ́,
má sì bá wọn rìn,
16nítorí ọ̀nà ibi ni ẹsẹ̀ wọn máa ń yá sí,
wọ́n a sì máa yára láti paniyan.
17Asán ni àwọ̀n tí eniyan dẹ sílẹ̀,
nígbà tí ẹyẹ tí a dẹ ẹ́ fún ń woni,
18ṣugbọn ẹ̀jẹ̀ ara wọn ni irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ lúgọ dè,
ìparun ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n lúgọ tí wọn ń retí.
19Bẹ́ẹ̀ ni ti àwọn tí wọ́n ń fi ipá kó ọrọ̀ jọ rí,
ọrọ̀ tí wọn fi ipá kójọ níí gba ẹ̀mí wọn.
Ọgbọ́n Ń pè
20Ọgbọ́n ń kígbe ní òpópónà,
ó ń pariwo láàrin ọjà,
21ó ń kígbe lórí odi ìlú,
ó ń sọ̀rọ̀ ní àwọn ẹnubodè ìlú, ó ní, #Owe 8:1-3
22“Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ óo ti pẹ́ tó ninu àìmọ̀kan yín?
Àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn yóo ti ní inú dídùn pẹ́ tó ninu ẹ̀gàn pípa wọn,
tí àwọn òmùgọ̀ yóo sì kórìíra ìmọ̀?
23Ẹ fetí sí ìbáwí mi,
n óo ṣí ọkàn mi payá fun yín,
n óo sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi ye yín.
24Nítorí pé mo ti ké títí, kò sì sí ẹni tí ó gbọ́,
mo ti na ọwọ́ si yín ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn,
25ẹ ti pa gbogbo ìmọ̀ràn mi tì,
ẹ kò sì gbọ́ ọ̀kankan ninu ìbáwí mi.
26Èmi náà óo sì máa fi yín rẹ́rìn-ín
nígbà tí ìdààmú bá dé ba yín,
n óo máa fi yín ṣe ẹlẹ́yà
nígbà tí ìpayà bá dé ba yín.
27Nígbà tí ìpayà bá dé ba yín bí ìjì,
tí ìdààmú dé ba yín bí ìjì líle,
tí ìpọ́njú ati ìrora bò yín mọ́lẹ̀.
28Ẹ óo ké pè mí nígbà náà,
ṣugbọn n kò ní dáhùn.
Ẹ óo wá mi láìsinmi,
ṣugbọn ẹ kò ní rí mi.
29Nítorí pé ẹ kórìíra ìmọ̀,
ẹ kò sì bẹ̀rù OLUWA.
30Ẹ kò fẹ́ ìmọ̀ràn mi,
ẹ sì kẹ́gàn gbogbo ìbáwí mi.
31Nítorí náà, ẹ óo jèrè iṣẹ́ yín,
ìwà burúkú yín yóo sì di àìsàn si yín lára.
32Àwọn aláìgbọ́n kú nítorí pé wọn kò gba ẹ̀kọ́
aibikita àwọn òmùgọ̀ ni yóo pa wọ́n run.
33Ṣugbọn ẹni tí ó gbọ́ tèmi,
yóo máa wà láìléwu,
yóo máa gbé pẹlu ìrọ̀rùn, láìsí ìpayà ibi.”

Currently Selected:

ÌWÉ ÒWE 1: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy