YouVersion Logo
Search Icon

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 28

28
Ohun tí Paulu Ṣe ní Erékùṣù Mẹlita
1Nígbà tí a ti gúnlẹ̀ ní alaafia tán ni a tó mọ̀ pé Mẹlita ni wọ́n ń pe erékùṣù náà. 2Àwọn ará ibẹ̀ ṣe ìtọ́jú wa lọpọlọpọ. Wọ́n fi ọ̀yàyà gba gbogbo wa. Wọ́n dáná fún wa nítorí pé òjò ti bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀, òtútù sì mú. 3Nígbà tí Paulu di ìdì igi kan, tí ó dà á sinu iná, bẹ́ẹ̀ ni paramọ́lẹ̀ kan yọ nígbà tí iná rà á, ló bá so mọ́ Paulu lọ́wọ́. 4Nígbà tí àwọn ará Mẹlita rí ejò náà tí ó ń ṣe dìrọ̀dìrọ̀ ní ọwọ́ Paulu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkunrin yìí. Ó yọ ninu ewu òkun, ṣugbọn Ọlọrun ẹ̀san kò gbà pé kí ó yè.” 5Paulu kàn gbọn ejò náà sinu iná ni, ohun burúkú kan kò sì ṣẹlẹ̀ sí i. 6Àwọn eniyan ń retí pé ọwọ́ rẹ̀ yóo wú, tabi pé lójijì yóo ṣubú lulẹ̀, yóo sì kú. Nígbà tí wọ́n retí títí, tí wọn kò rí i kí nǹkankan ṣe é, wọ́n yí èrò wọn pada, wọ́n ní, “Irúnmọlẹ̀ ni!”
7Ilẹ̀ tí ó wá yí wọn ká jẹ́ ti Pubiliusi, baálẹ̀ erékùṣù náà. Ó gbà wá sílé fún ọjọ́ mẹta, ó sì ṣe wá lálejò. 8Ní àkókò yìí baba Pubiliusi ń ṣàìsàn: ibà ń ṣe é, ó sì ń ya ìgbẹ́-ọ̀rìn. Paulu bá wọ iyàrá tọ̀ ọ́ lọ. Lẹ́yìn tí ó gbadura, ó gbé ọwọ́ lé e, ó sì wò ó sàn. 9Nígbà tí èyí ṣẹlẹ̀, àwọn yòókù tí ó ń ṣàìsàn ní erékùṣù náà bá ń wá sọ́dọ̀ Paulu, ó sì ń wò wọ́n sàn. 10Wọ́n yẹ́ wa sí pupọ. Nígbà tí a óo sì fi ṣíkọ̀, wọ́n fún wa ní àwọn nǹkan tí a lè nílò lọ́nà.
Paulu Dé Romu
11Lẹ́yìn oṣù mẹta tí a ti wà níbẹ̀, a wọ ọkọ̀ ojú omi Alẹkisandria kan tí ó ti dúró ní erékùṣù yìí fún ìgbà òtútù. Ó ní ère ìbejì níwájú rẹ̀. 12Nígbà tí a dé Sirakusi, a dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta. 13Láti ibẹ̀ a ṣíkọ̀, a dé Regiumu. Ní ọjọ́ keji, afẹ́fẹ́ kan láti gúsù fẹ́ wá, ni a bá tún ṣíkọ̀. Ní ọjọ́ kẹta a dé Puteoli. 14A rí àwọn onigbagbọ níbẹ̀. Wọ́n rọ̀ wá kí á dúró lọ́dọ̀ wọn, a bá ṣe ọ̀sẹ̀ kan níbẹ̀. Báyìí ni a ṣe dé Romu. 15Àwọn onigbagbọ ibẹ̀ ti gbọ́ ìròyìn wa. Wọ́n bá wá pàdé wa lọ́nà, wọ́n dé Ọjà Apiusi ati Ilé-èrò Mẹta. Nígbà tí Paulu rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, èyí sì dá a lọ́kàn le.
Paulu Waasu ní Romu
16Nígbà tí a wọ Romu, wọ́n gba Paulu láàyè láti wá ilé gbé pẹlu ọmọ-ogun kan tí wọ́n fi ṣọ́ ọ.
17Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta Paulu pe àwọn aṣiwaju àwọn Juu jọ. Nígbà tí ẹsẹ̀ wọn pé, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin alàgbà, n kò ṣe ohunkohun tí ó lòdì sí àwọn eniyan wa tabi sí àṣà àwọn baba ńlá wa tí wọ́n fi fi mí lé àwọn ará Romu lọ́wọ́ tí wọ́n sì fi mí sinu ẹ̀wọ̀n láti Jerusalẹmu. 18Nígbà tí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu mi, wọ́n fẹ́ dá mi sílẹ̀ nítorí wọn kò rí ohunkohun tí mo ṣe tí wọ́n fi lè dá mi lẹ́bi ikú. 19Ṣugbọn nígbà tí àwọn Juu kò gbà pé kí wọ́n dá mi sílẹ̀, kò sí ohun tí mo tún lè ṣe jù pé kí n gbé ẹjọ́ mi wá siwaju Kesari lọ. Kì í ṣe pé mo ní ẹjọ́ kankan láti bá orílẹ̀-èdè wa rò. #A. Apo 25:11 20Ìdí nìyí tí mo fi ranṣẹ pè yín láti ri yín kí n sì ba yín sọ̀rọ̀; nítorí ohun tí Israẹli ń retí ni wọ́n ṣe fi ẹ̀wọ̀n so mí báyìí.”
21Wọ́n dá a lóhùn pé, “A kò rí ìwé gbà nípa rẹ láti Judia; bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni ninu àwọn ará wa kò débí láti ròyìn rẹ tabi láti sọ̀rọ̀ rẹ ní ibi. 22A rò pé ó dára kí á gbọ́ ohun tí o ní lọ́kàn, nítorí pé ó ti dé etígbọ̀ọ́ wa pé níbi gbogbo ni àwọn eniyan lòdì sí ẹgbẹ́ tí ó yàtọ̀ yìí.”
23Wọ́n bá dá ọjọ́ tí wọn yóo wá fún un. Nígbà tí ọjọ́ pé, pupọ ninu wọn wá kí i. Ó bá dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀, ó ń fi tẹ̀dùntẹ̀dùn ṣe àlàyé ìjọba Ọlọrun fún wọn, ó sì ń fi ẹ̀rí tí ó wà ninu ìwé Òfin Mose ati ìwé wolii nípa Jesu hàn wọ́n láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. 24Àwọn mìíràn gba ohun tí ó sọ gbọ́, ṣugbọn àwọn mìíràn kò gbàgbọ́. 25Nígbà tí ohùn wọn kò dọ́gba láàrin ara wọn, wọ́n bá ń túká lọ. Paulu wá tún sọ gbolohun kan, ó ní, “Òtítọ́ ni Ẹ̀mí Mímọ́ sọ láti ẹnu wolii Aisaya sí àwọn baba-ńlá yín. 26Ó ní,
‘Lọ sọ fún àwọn eniyan yìí pé:
Ẹ óo fetí yín gbọ́, ṣugbọn kò ní ye yín;
Ẹ óo wò ó títí, ṣugbọn ẹ kò ní mọ̀ ọ́n.
27Nítorí ọkàn àwọn eniyan yìí kò ṣí; #Ais 6:9-10
wọ́n ti di alágbọ̀ọ́ya,
wọ́n ti dijú.
Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀,
wọn ìbá fi ojú wọn ríran,
wọn ìbá fetí gbọ́ràn,
òye ìbá yé wọn,
wọn ìbá yipada;
èmi ìbá sì wò wọ́n sàn.’
28“Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé a ti rán iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọrun yìí sí àwọn tí kì í ṣe Juu. Àwọn ní tiwọn yóo gbọ́.” 29Nígbà tí Paulu ti sọ báyìí tán, àwọn Juu túká, wọ́n ń bá ara wọn jiyàn kíkankíkan.
30Fún ọdún meji gbáko ni Paulu fi gbé ninu ilé tí ó gbà fúnra rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ń gba gbogbo àwọn tí ó ń wá rí i. 31Ó ń waasu ìjọba Ọlọrun. Ó ń kọ́ àwọn eniyan nípa Oluwa Jesu Kristi láì bẹ̀rù ohunkohun. Ẹnikẹ́ni kò sì dí i lọ́wọ́.

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy