1
JAKỌBU 1:2-3
Yoruba Bible
Ẹ̀yin ará mi, ẹ kà á sí ayọ̀ gidi nígbà tí oríṣìíríṣìí ìdánwò bá dé ba yín. Kí ẹ mọ̀ pé ìdánwò igbagbọ yín ń mú kí ẹ ní ìfaradà.
Compare
Explore JAKỌBU 1:2-3
2
JAKỌBU 1:5
Bí ẹnikẹ́ni bá wà ninu yín, tí ọgbọ́n kù díẹ̀ kí ó tó fún, kí olúwarẹ̀ bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọrun, yóo sì fún un. Nítorí Ọlọrun lawọ́, kì í sìí sìrègún.
Explore JAKỌBU 1:5
3
JAKỌBU 1:19
Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo fẹ́ kí ẹ mọ nǹkankan: eniyan níláti tètè gbọ́ ọ̀rọ̀, ṣugbọn kí ó lọ́ra láti désì pada, kí ó sì lọ́ra láti bínú.
Explore JAKỌBU 1:19
4
JAKỌBU 1:4
Ẹ níláti ní ìfaradà títí dé òpin, kí ẹ lè di pípé, kí ẹ sì ní ohun gbogbo lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, láìsí ìkùnà kankan.
Explore JAKỌBU 1:4
5
JAKỌBU 1:22
Ẹ máa fi ọ̀rọ̀ ìyìn rere ṣe ìwà hù; ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán. Bí ẹ bá ń gbọ́ lásán, ara yín ni ẹ̀ ń tàn jẹ.
Explore JAKỌBU 1:22
6
JAKỌBU 1:12
Ẹni tí ó bá fi ara da ìdánwò kú oríire, nítorí nígbà tí ó bá yege tán, yóo gba adé ìyè tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀.
Explore JAKỌBU 1:12
7
JAKỌBU 1:17
Láti òkè ni gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ẹ̀bùn pípé ti ń wá, a máa wá láti ọ̀dọ̀ Baba tí ó dá ìmọ́lẹ̀, baba tí kì í yí pada, tí irú òjìji tíí máa wà ninu ìṣípò pada kò sì sí ninu rẹ̀.
Explore JAKỌBU 1:17
8
JAKỌBU 1:23-24
Nítorí bí eniyan bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí kò fi ṣe ìwà hù, olúwarẹ̀ dàbí ẹni tí ó wo ojú ara rẹ̀ ninu dígí. Ó wo ara rẹ̀ dáradára, ó kúrò níbẹ̀, kíá ó ti gbàgbé bí ojú rẹ̀ ti rí.
Explore JAKỌBU 1:23-24
9
JAKỌBU 1:27
Ẹ̀sìn tí ó pé, tí kò lábàwọ́n níwájú Ọlọrun Baba ni pé kí eniyan máa ran àwọn ọmọ tí kò ní òbí ati àwọn opó lọ́wọ́ ninu ipò ìbànújẹ́ wọn, kí eniyan sì pa ara rẹ̀ mọ́ láìléèérí ninu ayé.
Explore JAKỌBU 1:27
10
JAKỌBU 1:13-14
Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìdánwò má ṣe sọ pé, “Láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ìdánwò yìí ti wá.” Nítorí kò sí ẹni tí ó lè fi nǹkan burúkú dán Ọlọrun wò. Ọlọrun náà kò sì jẹ́ fi nǹkan burúkú dán ẹnikẹ́ni wò. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn olukuluku ni ó ń tàn án, tí ó ń fa ìdánwò.
Explore JAKỌBU 1:13-14
11
JAKỌBU 1:9
Kí arakunrin tí ó jẹ́ mẹ̀kúnnù kí ó yọ̀ nígbà tí Ọlọrun bá gbé e ga.
Explore JAKỌBU 1:9
YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy
Home
Bible
Plans
Videos