1
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:18
Yoruba Bible
Nítorí pé ọpọlọpọ ọgbọ́n a máa mú ọpọlọpọ ìbànújẹ́ wá, ẹni tí ń fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀, ó ń fi kún ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ ni.
Compare
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:18
2
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:9
Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóo máa wà. Ohun tí a ti ṣe tẹ́lẹ̀ náà ni a óo tún máa ṣe, kò sí ohun titun kan ní ilé ayé.
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:9
3
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:8
Gbogbo nǹkan ní ń kó àárẹ̀ bá eniyan, ju bí ẹnu ti lè sọ lọ. Ìran kì í sú ojú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ kì í kún etí.
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:8
4
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:2-3
Asán ninu asán, bí ọ̀jọ̀gbọ́n ti wí, asán ninu asán, gbogbo rẹ̀ asán ni. Èrè kí ni eniyan ń jẹ ninu gbogbo làálàá rẹ̀, tí ó ń ṣe nílé ayé?
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:2-3
5
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:14
Mo ti wo gbogbo nǹkan tí eniyan ń ṣe láyé, wò ó, asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀.
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:14
6
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:4
Ìran kan ń kọjá lọ, òmíràn ń dé, ṣugbọn ayé wà títí laelae.
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:4
7
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:11
Kò sí ẹni tí ó ranti àwọn nǹkan àtijọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni, kò sì ní sí ẹni tí yóo ranti àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la.
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:11
8
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:17
Mo pinnu lọ́kàn mi láti mọ ohun tí ọgbọ́n jẹ́, ati láti mọ ohun tí ìwà wèrè ati ìwà òmùgọ̀ jẹ́. Mo wá wòye pé èyí pàápàá jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:17
YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy
Home
Bible
Plans
Videos