Zechariah 14:8-16

Sek 14:8-16 - Yio si ṣe li ọjọ na, omi iyè yio ti Jerusalemu ṣàn lọ; idajì wọn sihà kun ilà-õrun, ati idajì wọn sihà okun ẹhìn: nigbà ẹ̀run ati nigbà otutù ni yio ri bẹ̃.
Oluwa yio si jọba lori gbogbo aiye: li ọjọ na ni Oluwa kan yio wà, orukọ rẹ̀ yio si jẹ ọkan.
A o yi gbogbo ilẹ padà bi pẹtẹlẹ kan lati Geba de Rimmoni lapa gusu Jerusalemu: a o si gbe e soke, yio si gbe ipò rẹ̀, lati ibode Benjamini titi de ibi ibode ekini, de ibode igun nì, ati lati ile iṣọ Hananeeli de ibi ifunti waini ọba.
Enia yio si ma gbe ibẹ̀, kì yio si si iparun yanyan mọ; Ṣugbọn a o ma gbe Jerusalemu lailewu.
Eyi ni yio si jẹ àrun ti Oluwa yio fi kọlu gbogbo awọn enia ti o ti ba Jerusalemu ja; ẹran-ara wọn yio rù nigbati wọn duro li ẹsẹ̀ wọn, oju wọn yio si rà ni ihò wọn, ahọn wọn yio si jẹrà li ẹnu wọn.
Yio si ṣe li ọjọ na, irọkẹ̀kẹ nla lati ọdọ Oluwa wá yio wà lãrin wọn; nwọn o si dì ọwọ ara wọn mu, ọwọ rẹ̀ yio si dide si ọwọ ẹnikeji rẹ̀.
Juda pẹlu yio si jà ni Jerusalemu; ọrọ̀ gbogbo awọn keferi ti o wà kakiri li a o si kojọ, wurà, ati fàdakà, ati aṣọ, li ọpọlọpọ.
Bẹ̃ni àrun ẹṣin, ibãka, ràkumi, ati ti kẹtẹkẹtẹ, yio si wà, ati gbogbo ẹranko ti mbẹ ninu agọ wọnyi gẹgẹ bi àrun yi.
Yio si ṣe, olukuluku ẹniti o kù ninu gbogbo awọn orilẹ-ède ti o dide si Jerusalemu yio ma goke lọ lọdọdun lati sìn Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati lati pa àse agọ wọnni mọ.

Yio si ṣe li ọjọ na, omi iyè yio ti Jerusalemu ṣàn lọ; idajì wọn sihà kun ilà-õrun, ati idajì wọn sihà okun ẹhìn: nigbà ẹ̀run ati nigbà otutù ni yio ri bẹ̃. Oluwa yio si jọba lori gbogbo aiye: li ọjọ na ni Oluwa kan yio wà, orukọ rẹ̀ yio si jẹ ọkan. A o yi gbogbo ilẹ padà bi pẹtẹlẹ kan lati Geba de Rimmoni lapa gusu Jerusalemu: a o si gbe e soke, yio si gbe ipò rẹ̀, lati ibode Benjamini titi de ibi ibode ekini, de ibode igun nì, ati lati ile iṣọ Hananeeli de ibi ifunti waini ọba. Enia yio si ma gbe ibẹ̀, kì yio si si iparun yanyan mọ; Ṣugbọn a o ma gbe Jerusalemu lailewu. Eyi ni yio si jẹ àrun ti Oluwa yio fi kọlu gbogbo awọn enia ti o ti ba Jerusalemu ja; ẹran-ara wọn yio rù nigbati wọn duro li ẹsẹ̀ wọn, oju wọn yio si rà ni ihò wọn, ahọn wọn yio si jẹrà li ẹnu wọn. Yio si ṣe li ọjọ na, irọkẹ̀kẹ nla lati ọdọ Oluwa wá yio wà lãrin wọn; nwọn o si dì ọwọ ara wọn mu, ọwọ rẹ̀ yio si dide si ọwọ ẹnikeji rẹ̀. Juda pẹlu yio si jà ni Jerusalemu; ọrọ̀ gbogbo awọn keferi ti o wà kakiri li a o si kojọ, wurà, ati fàdakà, ati aṣọ, li ọpọlọpọ. Bẹ̃ni àrun ẹṣin, ibãka, ràkumi, ati ti kẹtẹkẹtẹ, yio si wà, ati gbogbo ẹranko ti mbẹ ninu agọ wọnyi gẹgẹ bi àrun yi. Yio si ṣe, olukuluku ẹniti o kù ninu gbogbo awọn orilẹ-ède ti o dide si Jerusalemu yio ma goke lọ lọdọdun lati sìn Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati lati pa àse agọ wọnni mọ.

Sek 14:8-16