Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Rom 8:26-34

Rom 8:26-34 - Bẹ̃ gẹgẹ li Ẹmí pẹlu si nràn ailera wa lọwọ: nitori a kò mọ̀ bi ã ti igbadura gẹgẹ bi o ti yẹ: ṣugbọn Ẹmí tikararẹ̀ nfi irora ti a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ fun wa.
Ẹniti o si nwá inu ọkàn wo, o mọ̀ ohun ti inu Ẹmí, nitoriti o mbẹbẹ fun awọn enia mimọ́ gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun.
Awa si mọ̀ pe ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ̀ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun, ani fun awọn ẹniti a pè gẹgẹ bi ipinnu rẹ̀.
Nitori awọn ẹniti o ti mọ̀ tẹlẹ, li o si ti yàn tẹlẹ lati ri bi aworan Ọmọ rẹ̀, ki on le jẹ akọbi larin awọn arakunrin pupọ.
Awọn ti o si ti yàn tẹlẹ, awọn li o si ti pè: awọn ẹniti o si ti pè, awọn li o si ti dalare: awọn ẹniti o si ti dalare, awọn li o si ti ṣe logo.

Njẹ kili awa o ha wi si nkan wọnyi? Bi Ọlọrun bá wà fun wa, tani yio kọ oju ija si wa?
Ẹniti kò da Ọmọ on tikararẹ̀ si, ṣugbọn ti o jọwọ rẹ̀ lọwọ fun gbogbo wa, yio ha ti ṣe ti kì yio fun wa li ohun gbogbo pẹlu rẹ̀ lọfẹ?
Tani yio ha kà ohunkohun si ọrùn awọn ayanfẹ Ọlọrun? Ihaṣe Ọlọrun ti ndare?
Tali ẹniti ndẹbi? Ihaṣe Kristi Jesu ti o kú, ki a sa kuku wipe ti a ti ji dide kuro ninu okú, ẹniti o si wà li ọwọ́ ọtun Ọlọrun, ti o si mbẹ̀bẹ fun wa?

Bẹ̃ gẹgẹ li Ẹmí pẹlu si nràn ailera wa lọwọ: nitori a kò mọ̀ bi ã ti igbadura gẹgẹ bi o ti yẹ: ṣugbọn Ẹmí tikararẹ̀ nfi irora ti a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ fun wa. Ẹniti o si nwá inu ọkàn wo, o mọ̀ ohun ti inu Ẹmí, nitoriti o mbẹbẹ fun awọn enia mimọ́ gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun. Awa si mọ̀ pe ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ̀ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun, ani fun awọn ẹniti a pè gẹgẹ bi ipinnu rẹ̀. Nitori awọn ẹniti o ti mọ̀ tẹlẹ, li o si ti yàn tẹlẹ lati ri bi aworan Ọmọ rẹ̀, ki on le jẹ akọbi larin awọn arakunrin pupọ. Awọn ti o si ti yàn tẹlẹ, awọn li o si ti pè: awọn ẹniti o si ti pè, awọn li o si ti dalare: awọn ẹniti o si ti dalare, awọn li o si ti ṣe logo. Njẹ kili awa o ha wi si nkan wọnyi? Bi Ọlọrun bá wà fun wa, tani yio kọ oju ija si wa? Ẹniti kò da Ọmọ on tikararẹ̀ si, ṣugbọn ti o jọwọ rẹ̀ lọwọ fun gbogbo wa, yio ha ti ṣe ti kì yio fun wa li ohun gbogbo pẹlu rẹ̀ lọfẹ? Tani yio ha kà ohunkohun si ọrùn awọn ayanfẹ Ọlọrun? Ihaṣe Ọlọrun ti ndare? Tali ẹniti ndẹbi? Ihaṣe Kristi Jesu ti o kú, ki a sa kuku wipe ti a ti ji dide kuro ninu okú, ẹniti o si wà li ọwọ́ ọtun Ọlọrun, ti o si mbẹ̀bẹ fun wa?

Rom 8:26-34

Rom 8:26-34
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò