Ifi 5:13-14

Gbogbo ẹda ti o si mbẹ li ọrun, ati lori ilẹ aiye, ati nisalẹ ilẹ, ati irú awọn ti mbẹ ninu okun, ati gbogbo awọn ti mbẹ ninu wọn, ni mo gbọ́ ti nwipe, Ki a fi ibukún ati ọlá, ati ogo, ati agbara, fun ẹniti o joko lori itẹ́ ati fun Ọdọ-Agutan na lai ati lailai. Awọn ẹda alãye mẹrin na wipe; Amin. Awọn àgba mẹrinlelogun na wolẹ, nwọn si foribalẹ fun ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai.
Ifi 5:13-14