Psalms 98:1-9

Ẹ kọrin titun si Oluwa; nitoriti o ti ṣe ohun iyanu: ọwọ ọtún rẹ̀, ati apa rẹ̀ mimọ́ li o ti mu igbala wa fun ara rẹ̀. Oluwa ti sọ igbala rẹ̀ di mimọ̀: ododo rẹ̀ li o ti fi hàn nigbangba li ojú awọn keferi. O ti ranti ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ si awọn ara ile Israeli: gbogbo opin aiye ti ri igbala Ọlọrun wa. Ẹ ho iho ayọ̀ si Oluwa, gbogbo aiye: ẹ ho yè, ẹ yọ̀, ki ẹ si ma kọrin iyìn. Ẹ ma fi duru kọrin si Oluwa, ati duru pẹlu ohùn orin-mimọ́. Pẹlu ipè ati ohùn fere, ẹ ho iho ayọ̀ niwaju Oluwa, Ọba. Jẹ ki okun ki o ma ho pẹlu ikún rẹ̀; aiye, ati awọn ti mbẹ ninu rẹ̀. Jẹ ki odò ki o ma ṣapẹ, ki awọn òke ki o ma ṣe ajọyọ̀. Niwaju Oluwa; nitori ti mbọwa iṣe idajọ aiye: pẹlu ododo ni yio fi ṣe idajọ aiye, ati awọn orilẹ-ède li aiṣègbe.
O. Daf 98:1-9