Psalms 95:1-7

ẸWÁ, ẹ jẹ ki a kọrin si Oluwa: ẹ jẹ ki a hó iho ayọ̀ si apata igbala wa. Ẹ jẹ ki a fi ọpẹ wá si iwaju rẹ̀, ki a si fi orin mimọ́ hó iho ayọ̀ si ọdọ rẹ̀. Nitori Oluwa, Ọlọrun ti o tobi ni, ati Ọba ti o tobi jù gbogbo oriṣa lọ, Ni ikawọ ẹniti ibi ọgbun ilẹ wà: giga awọn òke nla ni tirẹ̀ pẹlu. Tirẹ̀ li okun, on li o si dá a: ọwọ rẹ̀ li o si dá iyangbẹ ilẹ. Ẹ wá, ẹ jẹ ki a wolẹ, ki a tẹriba: ẹ jẹ ki a kunlẹ niwaju Oluwa, Ẹlẹda wa. Nitori on li Ọlọrun wa; awa si li enia papa rẹ̀, ati agutan ọwọ rẹ̀. Loni bi ẹnyin o ba gbọ́ ohùn rẹ̀
O. Daf 95:1-7