Psaumes 85:1-7

OLUWA, iwọ ti nṣe oju rere si ilẹ rẹ: iwọ ti mu igbekun Jakobu pada bọ̀. Iwọ ti dari aiṣedede awọn enia rẹ jì, iwọ ti bò gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ. Iwọ ti mu gbogbo ibinu rẹ kuro: iwọ ti yipada kuro ninu gbigbona ibinu rẹ. Yi wa pada, Ọlọrun igbala wa, ki o si mu ibinu rẹ si wa ki o dá. Iwọ o binu si wa titi lai? iwọ o fà ibinu rẹ jade lati irandiran? Iwọ kì yio tun mu wa sọji: ki awọn enia rẹ ki o ma yọ̀ ninu rẹ? Oluwa fi ãnu rẹ hàn fun wa, ki o si fun wa ni igbala rẹ.
O. Daf 85:1-7