Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Psalms 8:1-9

O. Daf 8:1-9 - OLUWA, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyìn to ni gbogbo aiye! iwọ ti o gbé ogo rẹ kà ori awọn ọrun.
Lati ẹnu awọn ọmọ-ọwọ ati ọmọ-ọmu ni iwọ ti ṣe ilana agbara, nitori awọn ọta rẹ, nitori ki iwọ ki o le mu ọta olugbẹsan nì dakẹjẹ.
Nigbati mo rò ọrun rẹ, iṣẹ ika rẹ, oṣupa ati irawọ, ti iwọ ti ṣe ilana silẹ.
Kili enia, ti iwọ fi nṣe iranti rẹ̀? ati ọmọ enia, ti iwọ fi mbẹ̀ ẹ wò.
Iwọ sa da a li onirẹlẹ diẹ jù Ọlọrun lọ, iwọ si ti fi ogo ati ọlá de e li ade.
Iwọ mu u jọba iṣẹ ọwọ rẹ; iwọ si ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀;
Awọn agutan ati awọn malu pẹlu, ati awọn ẹranko igbẹ;
Awọn ẹiyẹ oju ọrun, ati awọn ẹja okun, ti o nkọja lọ nipa ọ̀na okun.
Oluwa, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyìn to ni gbogbo aiye!

OLUWA, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyìn to ni gbogbo aiye! iwọ ti o gbé ogo rẹ kà ori awọn ọrun. Lati ẹnu awọn ọmọ-ọwọ ati ọmọ-ọmu ni iwọ ti ṣe ilana agbara, nitori awọn ọta rẹ, nitori ki iwọ ki o le mu ọta olugbẹsan nì dakẹjẹ. Nigbati mo rò ọrun rẹ, iṣẹ ika rẹ, oṣupa ati irawọ, ti iwọ ti ṣe ilana silẹ. Kili enia, ti iwọ fi nṣe iranti rẹ̀? ati ọmọ enia, ti iwọ fi mbẹ̀ ẹ wò. Iwọ sa da a li onirẹlẹ diẹ jù Ọlọrun lọ, iwọ si ti fi ogo ati ọlá de e li ade. Iwọ mu u jọba iṣẹ ọwọ rẹ; iwọ si ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀; Awọn agutan ati awọn malu pẹlu, ati awọn ẹranko igbẹ; Awọn ẹiyẹ oju ọrun, ati awọn ẹja okun, ti o nkọja lọ nipa ọ̀na okun. Oluwa, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyìn to ni gbogbo aiye!

O. Daf 8:1-9

Psalms 8:1-9
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò