Psalm 77:1-10

EMI fi ohùn mi kigbe si Ọlọrun, ani si Ọlọrun ni mo fi ohùn mi kepè; o si fi eti si mi. Li ọjọ ipọnju mi emi ṣe afẹri Ọlọrun: ọwọ mi nnà li oru, kò si rẹ̀ silẹ: ọkàn mi kọ̀ ati tù ninu. Emi ranti Ọlọrun, emi kẹdun: emi ṣe aroye, ẹmi mi si rẹ̀wẹsi. Iwọ kò fẹ ki emi ki o fi oju ba orun: ẹnu yọ mi tobẹ̃ ti emi kò le sọ̀rọ. Emi ti nrò ọjọ atijọ, ọdun igbani. Mo ranti orin mi li oru: emi mba aiya mi sọ̀rọ: ọkàn mi si nṣe awari jọjọ. Oluwa yio ha ṣa ni tì lailai? kì o si ṣe oju rere mọ́? Anu rẹ̀ ha lọ lailai? ileri rẹ̀ ha yẹ̀ titi lai? Ọlọrun ha gbagbe lati ṣe oju rere? ninu ibinu rẹ̀ o ha sé irọnu ãnu rẹ̀ mọ́? Emi wipe, Eyi li ailera mi! eyi li ọdun ọwọ ọtún Ọga-ogo!
O. Daf 77:1-10