Psalm 40:1-3

NI diduro emi duro de Oluwa; o si dẹti si mi, o si gbohun ẹkún mi. O si mu mi gòke pẹlu lati inu iho iparun jade wá, lati inu erupẹ ẹrẹ̀, o si fi ẹsẹ mi ka ori apata, o si fi iṣisẹ mi lelẹ. O si fi orin titun si mi li ẹnu, ani orin iyìn si Ọlọrun wa: ọ̀pọ enia ni yio ri i, ti yio si bẹ̀ru, ti yio si gbẹkẹle Oluwa.
O. Daf 40:1-3