Kiye si i, oju Oluwa mbẹ lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, lara awọn ti nreti ninu ãnu rẹ̀;
Lati gba ọkàn wọn la lọwọ ikú, ati lati pa wọn mọ́ lãye ni igba ìyan.
Ọkàn wa duro de Oluwa: on ni iranlọwọ wa ati asà wa.
Nitori ti ọkàn wa yio yọ̀ niti rẹ̀, nitori ti awa ti gbẹkẹle orukọ rẹ̀ mimọ́.