Psalms 3:1-8

OLUWA, awọn ti nyọ mi li ẹnu ti npọ̀ to yi! ọ̀pọlọpọ li awọn ti o dide si mi. Ọ̀pọlọpọ li awọn ti o nwi niti ọkàn mi pe, Iranlọwọ kò si fun u nipa ti Ọlọrun. Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li asà fun mi; ogo mi; ati olugbe ori mi soke. Emi fi ohùn mi kigbe si Oluwa, o si gbohùn mi lati òke mimọ́ rẹ̀ wá. Emi dubulẹ, mo si sùn; mo si ji; nitori ti Oluwa tì mi lẹhin, Emi kì yio bẹ̀ru ọ̀pọlọpọ enia, ti nwọn rọ̀gba yi mi ka. Dide Oluwa; gbà mi, Ọlọrun mi: nitori iwọ li o lù gbogbo awọn ọta mi li egungun ẹrẹkẹ; iwọ si ká ehin awọn enia buburu. Ti Oluwa ni igbala: ibukún rẹ si mbẹ lara awọn enia rẹ.
O. Daf 3:1-8