Psalms 127:1-5

BIKOṢEPE Oluwa ba kọ́ ile na, awọn ti nkọ́ ọ nṣiṣẹ lasan: bikoṣepe Oluwa ba pa ilu mọ́, oluṣọ ji lasan. Asan ni fun ẹnyin ti ẹ dide ni kutukutu lati pẹ iṣiwọ, lati jẹ onjẹ lãlã: bẹ̃li o nfi ire fun olufẹ rẹ̀ loju orun. Kiyesi i, awọn ọmọ ni ini Oluwa: ọmọ inu si li ère rẹ̀. Bi ọfà ti ri li ọwọ alagbara, bẹ̃li awọn ọmọ igbà èwe rẹ. Ibukún ni fun ọkunrin na ti apo rẹ̀ kún fun wọn: oju kì yio tì wọn, ṣugbọn nwọn o ṣẹgun awọn ọta li ẹnu ọ̀na.
O. Daf 127:1-5