Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Psalm 119:1-16

O. Daf 119:1-16 - IBUKÚN ni fun awọn ẹniti o pé li ọ̀na na, ti nrìn ninu ofin Oluwa.
Ibukún ni fun awọn ti npa ẹri rẹ̀ mọ́, ti si nwá a kiri tinu-tinu gbogbo.
Nwọn kò dẹṣẹ pẹlu: nwọn nrìn li ọ̀na rẹ̀.
Iwọ ti paṣẹ fun wa lati pa ẹkọ́ rẹ mọ́ gidigidi.
Ọ̀na mi iba jẹ là silẹ lati ma pa ilana rẹ mọ́!
Nigbana li oju kì yio tì mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo.
Emi o ma fi aiya diduro-ṣinṣin yìn ọ, nigbati emi ba ti kọ́ idajọ ododo rẹ.
Emi o pa ilana rẹ mọ́: máṣe kọ̀ mi silẹ patapata.

Nipa ewo li ọdọmọkunrin yio fi mu ọ̀na rẹ̀ mọ́? nipa ikiyesi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.
Tinu-tinu mi gbogbo li emi fi ṣe afẹri rẹ: máṣe jẹ ki emi ṣina kuro ninu aṣẹ rẹ.
Ọ̀rọ rẹ ni mo pamọ́ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ̀ si ọ.
Olubukún ni iwọ, Oluwa: kọ́ mi ni ilana rẹ.
Ẹnu mi li emi fi nsọ gbogbo idajọ ẹnu rẹ.
Emi ti nyọ̀ li ọ̀na ẹri rẹ, bi lori oniruru ọrọ̀.
Emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ emi o si ma juba ọ̀na rẹ.
Emi o ma ṣe inu-didùn ninu ilana rẹ: emi kì yio gbagbe ọ̀rọ rẹ.

IBUKÚN ni fun awọn ẹniti o pé li ọ̀na na, ti nrìn ninu ofin Oluwa. Ibukún ni fun awọn ti npa ẹri rẹ̀ mọ́, ti si nwá a kiri tinu-tinu gbogbo. Nwọn kò dẹṣẹ pẹlu: nwọn nrìn li ọ̀na rẹ̀. Iwọ ti paṣẹ fun wa lati pa ẹkọ́ rẹ mọ́ gidigidi. Ọ̀na mi iba jẹ là silẹ lati ma pa ilana rẹ mọ́! Nigbana li oju kì yio tì mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo. Emi o ma fi aiya diduro-ṣinṣin yìn ọ, nigbati emi ba ti kọ́ idajọ ododo rẹ. Emi o pa ilana rẹ mọ́: máṣe kọ̀ mi silẹ patapata. Nipa ewo li ọdọmọkunrin yio fi mu ọ̀na rẹ̀ mọ́? nipa ikiyesi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Tinu-tinu mi gbogbo li emi fi ṣe afẹri rẹ: máṣe jẹ ki emi ṣina kuro ninu aṣẹ rẹ. Ọ̀rọ rẹ ni mo pamọ́ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ̀ si ọ. Olubukún ni iwọ, Oluwa: kọ́ mi ni ilana rẹ. Ẹnu mi li emi fi nsọ gbogbo idajọ ẹnu rẹ. Emi ti nyọ̀ li ọ̀na ẹri rẹ, bi lori oniruru ọrọ̀. Emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ emi o si ma juba ọ̀na rẹ. Emi o ma ṣe inu-didùn ninu ilana rẹ: emi kì yio gbagbe ọ̀rọ rẹ.

O. Daf 119:1-16

Psalm 119:1-16
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò