Psalms 111:1-6

Ẹ ma yìn Oluwa. Emi o ma yìn Oluwa tinutinu mi, ninu ijọ awọn ẹni diduro-ṣinṣin, ati ni ijọ enia. Iṣẹ Oluwa tobi, iwa-kiri ni fun gbogbo awọn ti o ni ifẹ rẹ̀ ninu. Iṣe rẹ̀ li ọlá on ogo, ododo rẹ̀ si duro lailai. O ṣe iṣẹ iyanu rẹ̀ ni iranti: olore-ọfẹ́ li Oluwa o si kún fun ãnu. O ti fi onjẹ fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀: yio ranti majẹmu rẹ̀ lailai. O ti fi iṣẹ agbara rẹ̀ hàn awọn enia rẹ̀, ki o le fun wọn ni ilẹ-ini awọn keferi.
O. Daf 111:1-6