Proverbs 21:1-31

Owe 21:1-31 - AIYA ọba mbẹ lọwọ Oluwa bi odò omi; on a si dari rẹ̀ si ìbikibi ti o wù u.
Gbogbo ọ̀na enia li o dara li oju ara rẹ̀: ṣugbọn Oluwa li o nṣe amọ̀na ọkàn.
Lati ṣe ododo ati idajọ, o ṣe itẹwọgba fun Oluwa jù ẹbọ lọ.
Gangan oju, ati igberaga aiya, ati itulẹ̀ enia buburu, ẹ̀ṣẹ ni.
Ìronu alãpọn si kiki ọ̀pọ ni; ṣugbọn ti olukuluku ẹniti o yara, si kiki aini ni.
Ini iṣura nipa ahọn eke, o jẹ ẽmi ti a ntì sihin tì sọhun lọwọ awọn ti nwá ikú kiri.
Iwa-agbara awọn enia buburu ni yio pa wọn run: nitori ti nwọn kọ̀ lati ṣe idajọ.
Ẹnikẹni ti o nrìn ọ̀na ayidayida, enia buburu ni; ṣugbọn oninu funfun ni iṣẹ rẹ̀ tọ́.
O san lati joko ni igun òke àja, jù pẹlu onija obinrin lọ ninu ile ajumọgbe.
Ọkàn enia buburu nwá ibi kiri: aladugbo rẹ̀ kò ri ojurere li oju rẹ̀.
Nigbati a ba jẹ ẹlẹgàn ni ìya, a sọ òpe di ọlọgbọ́n: nigbati a ba si nkọ́ ọlọgbọ́n, on o ma ni ìmọ.
Olododo kiyesi ile enia buburu: pe ẹnikan wà ti yio bì enia buburu ṣubu sinu iparun.
Ẹnikẹni ti o ba di eti rẹ̀ si igbe olupọnju, ontikararẹ̀ yio ke pẹlu: ṣugbọn a kì yio gbọ́.
Ọrẹ ikọkọ, o tù ibinu: ati ẹ̀bun ni iṣẹpo-aṣọ, o tù ibinu lile.
Ayọ̀ ni fun olododo lati ṣe idajọ: ṣugbọn iparun ni fun awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.
Ẹniti o ba yà kuro li ọ̀na oye, yio ma gbe inu ijọ awọn okú.
Ẹniti o ba fẹ afẹ, yio di talaka: ẹniti o fẹ ọti-waini pẹlu ororo kò le lọrọ̀.
Enia buburu ni yio ṣe owo-irapada fun olododo, ati olurekọja ni ipò ẹni diduro-ṣinṣin.
O san lati joko li aginju jù pẹlu onija obinrin ati oṣónu lọ.
Iṣura fifẹ ati ororo wà ni ibugbe ọlọgbọ́n; ṣugbọn enia aṣiwère ná a bajẹ.
Ẹniti o ba tẹle ododo ati ãnu, a ri ìye, ododo, ati ọlá.
Ọlọgbọ́n gùn odi ilu awọn alagbara, a si fi idi agbara igbẹkẹle rẹ̀ jalẹ̀.
Ẹnikẹni ti o ba pa ẹnu ati ahọn rẹ̀ mọ́, o pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kuro ninu iyọnu.
Agberaga ati agidi ẹlẹgàn li orukọ rẹ̀, ẹniti nhùwa ninu ibinu pupọpupọ.
Ifẹ ọlẹ pa a; nitoriti, ọwọ rẹ̀ kọ̀ iṣẹ ṣiṣe.
O nfi ilara ṣojukokoro ni gbogbo ọjọ: ṣugbọn olododo a ma fi funni kì si idawọduro.
Ẹbọ enia buburu, irira ni: melomelo ni nigbati o mu u wá ti on ti ìwakiwa rẹ̀?
Ẹlẹri eke yio ṣegbe: ṣugbọn ẹniti o gbọ́, yio ma sọ̀rọ li aiyannu.
Enia buburu gbè oju rẹ̀ le: ṣugbọn ẹni iduro-ṣinṣin li o nmu ọ̀na rẹ̀ tọ̀.
Kò si ọgbọ́n, kò si imoye, tabi ìgbimọ si Oluwa.
A mura ẹṣin silẹ de ọjọ ogun: ṣugbọn iṣẹgun lati ọwọ Oluwa ni.

AIYA ọba mbẹ lọwọ Oluwa bi odò omi; on a si dari rẹ̀ si ìbikibi ti o wù u. Gbogbo ọ̀na enia li o dara li oju ara rẹ̀: ṣugbọn Oluwa li o nṣe amọ̀na ọkàn. Lati ṣe ododo ati idajọ, o ṣe itẹwọgba fun Oluwa jù ẹbọ lọ. Gangan oju, ati igberaga aiya, ati itulẹ̀ enia buburu, ẹ̀ṣẹ ni. Ìronu alãpọn si kiki ọ̀pọ ni; ṣugbọn ti olukuluku ẹniti o yara, si kiki aini ni. Ini iṣura nipa ahọn eke, o jẹ ẽmi ti a ntì sihin tì sọhun lọwọ awọn ti nwá ikú kiri. Iwa-agbara awọn enia buburu ni yio pa wọn run: nitori ti nwọn kọ̀ lati ṣe idajọ. Ẹnikẹni ti o nrìn ọ̀na ayidayida, enia buburu ni; ṣugbọn oninu funfun ni iṣẹ rẹ̀ tọ́. O san lati joko ni igun òke àja, jù pẹlu onija obinrin lọ ninu ile ajumọgbe. Ọkàn enia buburu nwá ibi kiri: aladugbo rẹ̀ kò ri ojurere li oju rẹ̀. Nigbati a ba jẹ ẹlẹgàn ni ìya, a sọ òpe di ọlọgbọ́n: nigbati a ba si nkọ́ ọlọgbọ́n, on o ma ni ìmọ. Olododo kiyesi ile enia buburu: pe ẹnikan wà ti yio bì enia buburu ṣubu sinu iparun. Ẹnikẹni ti o ba di eti rẹ̀ si igbe olupọnju, ontikararẹ̀ yio ke pẹlu: ṣugbọn a kì yio gbọ́. Ọrẹ ikọkọ, o tù ibinu: ati ẹ̀bun ni iṣẹpo-aṣọ, o tù ibinu lile. Ayọ̀ ni fun olododo lati ṣe idajọ: ṣugbọn iparun ni fun awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ. Ẹniti o ba yà kuro li ọ̀na oye, yio ma gbe inu ijọ awọn okú. Ẹniti o ba fẹ afẹ, yio di talaka: ẹniti o fẹ ọti-waini pẹlu ororo kò le lọrọ̀. Enia buburu ni yio ṣe owo-irapada fun olododo, ati olurekọja ni ipò ẹni diduro-ṣinṣin. O san lati joko li aginju jù pẹlu onija obinrin ati oṣónu lọ. Iṣura fifẹ ati ororo wà ni ibugbe ọlọgbọ́n; ṣugbọn enia aṣiwère ná a bajẹ. Ẹniti o ba tẹle ododo ati ãnu, a ri ìye, ododo, ati ọlá. Ọlọgbọ́n gùn odi ilu awọn alagbara, a si fi idi agbara igbẹkẹle rẹ̀ jalẹ̀. Ẹnikẹni ti o ba pa ẹnu ati ahọn rẹ̀ mọ́, o pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kuro ninu iyọnu. Agberaga ati agidi ẹlẹgàn li orukọ rẹ̀, ẹniti nhùwa ninu ibinu pupọpupọ. Ifẹ ọlẹ pa a; nitoriti, ọwọ rẹ̀ kọ̀ iṣẹ ṣiṣe. O nfi ilara ṣojukokoro ni gbogbo ọjọ: ṣugbọn olododo a ma fi funni kì si idawọduro. Ẹbọ enia buburu, irira ni: melomelo ni nigbati o mu u wá ti on ti ìwakiwa rẹ̀? Ẹlẹri eke yio ṣegbe: ṣugbọn ẹniti o gbọ́, yio ma sọ̀rọ li aiyannu. Enia buburu gbè oju rẹ̀ le: ṣugbọn ẹni iduro-ṣinṣin li o nmu ọ̀na rẹ̀ tọ̀. Kò si ọgbọ́n, kò si imoye, tabi ìgbimọ si Oluwa. A mura ẹṣin silẹ de ọjọ ogun: ṣugbọn iṣẹgun lati ọwọ Oluwa ni.

Owe 21:1-31