Owe 18:1-8

ẸNITI o yà ara rẹ̀ sọtọ̀ yio lepa ifẹ ara rẹ̀, yio si kọju ìja nla si ohunkohun ti iṣe ti oye. Aṣiwère kò ni inu-didùn si imoye, ṣugbọn ki o le fi aiya ara rẹ̀ hàn. Nigbati enia-buburu ba de, nigbana ni ẹ̀gan de, ati pẹlu ẹ̀gan ni itiju. Ọ̀rọ ẹnu enia dabi omi jijìn, orisun ọgbọ́n bi odò ṣiṣàn. Kò dara lati ṣe ojuṣãju enia-buburu, lati bì olododo ṣubu ni idajọ. Ete aṣiwère bọ sinu ìja, ẹnu rẹ̀ a si ma pè ìna wá. Ẹnu aṣiwère ni iparun rẹ̀, ète rẹ̀ si ni ikẹkùn ọkàn rẹ̀. Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ.
Owe 18:1-8