Nipa ãnu ati otitọ a bò ẹ̀ṣẹ mọlẹ; ati nipa ibẹ̀ru Oluwa, enia a kuro ninu ibi.
Nigbati ọ̀na enia ba wù Oluwa, On a mu awọn ọtá rẹ̀ pãpa wà pẹlu rẹ̀ li alafia.
Diẹ pẹlu ododo, o san jù ọrọ̀ nla lọ laisi ẹtọ́.
Aiya enia ni ngbìmọ ọ̀na rẹ̀, ṣugbọn Oluwa li o ntọ́ itẹlẹ rẹ̀.