Ẹ jẹ ki ipamọra nyin di mimọ̀ fun gbogbo enia. Oluwa mbẹ nitosi.
Ẹ máṣe aniyàn ohunkohun; ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹbẹ pẹlu idupẹ, ẹ mã fi ìbere nyin hàn fun Ọlọrun.
Ati alafia Ọlọrun, ti o jù ìmọran gbogbo lọ, yio ṣọ ọkàn ati ero nyin ninu Kristi Jesu.