FILIPI 4:4-7

Ẹ mã yọ̀ ninu Oluwa nigbagbogbo: mo si tún wi, Ẹ mã yọ̀. Ẹ jẹ ki ipamọra nyin di mimọ̀ fun gbogbo enia. Oluwa mbẹ nitosi. Ẹ máṣe aniyàn ohunkohun; ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹbẹ pẹlu idupẹ, ẹ mã fi ìbere nyin hàn fun Ọlọrun. Ati alafia Ọlọrun, ti o jù ìmọran gbogbo lọ, yio ṣọ ọkàn ati ero nyin ninu Kristi Jesu.
Filp 4:4-7