Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Filp 3:12-21

Filp 3:12-21 - Kì iṣe pe ọwọ mi ti tẹ ẹ na, tabi mo ti di pipé: ṣugbọn emi nlepa nṣo, bi ọwọ́ mi yio le tẹ̀ ère na, nitori eyiti a ti di mi mu pẹlu, lati ọdọ Kristi Jesu wá.
Ará emi kò kà ara mi si ẹniti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ na: ṣugbọn ohun kan yi li emi nṣe, emi ngbagbé awọn nkan ti o wà lẹhin, mo si nnàgà wò awọn nkan ti o wà niwaju,
Emi nlepa lati de opin ire-ije nì fun ère ìpe giga Ọlọrun ninu Kristi Jesu.
Nitorina, ẹ jẹ ki iye awa ti iṣe ẹni pipé ni ero yi: bi ẹnyin bá si ni ero miran ninu ohunkohun, eyi na pẹlu ni Ọlọrun yio fi hàn nyin.
Kiki pe, ibiti a ti de na, ẹ jẹ ki a mã rìn li oju ọna kanna, ki a ni ero kanna.
Ará, ẹ jumọ ṣe afarawe mi, ẹ si ṣe akiyesi awọn ti nrìn bẹ̃, ani bi ẹ ti ni wa fun apẹrẹ.
(Nitori ọ̀pọlọpọ ni nrìn, nipasẹ awọn ẹniti mo ti nwi fun nyin nigbakugba, ani, ti mo si nsọkun bi mo ti nwi fun nyin nisisiyi, pe, ọtá agbelebu Kristi ni nwọn:
Igbẹhin ẹniti iṣe iparun, ikùn ẹniti iṣe ọlọrun wọn, ati ogo ẹniti o wà ninu itiju wọn, awọn ẹniti ntọju ohun aiye.)
Nitori ilu-ibilẹ wa mbẹ li ọrun: lati ibiti awa pẹlu gbé nfojusọna fun Olugbala, Jesu Kristi Oluwa:
Ẹniti yio sọ ara irẹlẹ wa di ọ̀tun ki o le bá ara ogo rẹ̀ mu, gẹgẹ bi iṣẹ-agbara nipasẹ eyiti on le fi tẹ ori ohun gbogbo ba fun ara rẹ̀.

Kì iṣe pe ọwọ mi ti tẹ ẹ na, tabi mo ti di pipé: ṣugbọn emi nlepa nṣo, bi ọwọ́ mi yio le tẹ̀ ère na, nitori eyiti a ti di mi mu pẹlu, lati ọdọ Kristi Jesu wá. Ará emi kò kà ara mi si ẹniti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ na: ṣugbọn ohun kan yi li emi nṣe, emi ngbagbé awọn nkan ti o wà lẹhin, mo si nnàgà wò awọn nkan ti o wà niwaju, Emi nlepa lati de opin ire-ije nì fun ère ìpe giga Ọlọrun ninu Kristi Jesu. Nitorina, ẹ jẹ ki iye awa ti iṣe ẹni pipé ni ero yi: bi ẹnyin bá si ni ero miran ninu ohunkohun, eyi na pẹlu ni Ọlọrun yio fi hàn nyin. Kiki pe, ibiti a ti de na, ẹ jẹ ki a mã rìn li oju ọna kanna, ki a ni ero kanna. Ará, ẹ jumọ ṣe afarawe mi, ẹ si ṣe akiyesi awọn ti nrìn bẹ̃, ani bi ẹ ti ni wa fun apẹrẹ. (Nitori ọ̀pọlọpọ ni nrìn, nipasẹ awọn ẹniti mo ti nwi fun nyin nigbakugba, ani, ti mo si nsọkun bi mo ti nwi fun nyin nisisiyi, pe, ọtá agbelebu Kristi ni nwọn: Igbẹhin ẹniti iṣe iparun, ikùn ẹniti iṣe ọlọrun wọn, ati ogo ẹniti o wà ninu itiju wọn, awọn ẹniti ntọju ohun aiye.) Nitori ilu-ibilẹ wa mbẹ li ọrun: lati ibiti awa pẹlu gbé nfojusọna fun Olugbala, Jesu Kristi Oluwa: Ẹniti yio sọ ara irẹlẹ wa di ọ̀tun ki o le bá ara ogo rẹ̀ mu, gẹgẹ bi iṣẹ-agbara nipasẹ eyiti on le fi tẹ ori ohun gbogbo ba fun ara rẹ̀.

Filp 3:12-21

Filp 3:12-21
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò