Nitori, niti emi, lati wà lãye jẹ Kristi, lati kú jẹ ere.
Ṣugbọn bi lati wà lãye ninu ara ba jẹ eso iṣẹ mi, nigbana ohun ti emi o yàn, emi kò mọ.
Ṣugbọn emi mbẹ ni iyemeji, mo ni ifẹ lati lọ ati lati wà lọdọ Kristi; nitori o dara pupọ ju:
Sibẹ lati wà ninu ara jẹ anfani nitori ti nyin.