Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Micah 6:1-8

Mik 6:1-8 - Ẹ gbọ́ nisisiyi ohun ti Oluwa wi; Dide, ba oke nla wijọ, si jẹ ki oke kékèké gbohùn rẹ.
Ẹ gbọ́ ẹjọ Oluwa, ẹnyin oke-nla, ati ẹnyin ipilẹ ilẹ̀ aiye: nitori Oluwa mba awọn enia rẹ̀ wijọ, yio si ba Israeli rojọ.
Enia mi, kini mo fi ṣe ọ? ati ninu kini mo fi da ọ li agara? dahùn si i.
Nitori mo ti mu ọ goke lati ilẹ Egipti wá, mo si rà ọ padà lati ile ẹrú wá; mo si rán Mose, Aaroni, ati Miriamu siwaju rẹ.
Enia mi, ranti nisisiyi ohun ti Balaki ọba Moabu gbèro, ati ohun ti Balaamu ọmọ Beori dá a lohùn lati Ṣittimu titi de Gilgali; ki ẹ ba le mọ̀ ododo Oluwa.

Kini emi o ha mu wá siwaju Oluwa, ti emi o fi tẹ̀ ara mi ba niwaju Ọlọrun giga? ki emi ha wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọrẹ-ẹbọ sisun, pẹlu ọmọ malu ọlọdún kan?
Inu Oluwa yio ha dùn si ẹgbẹgbẹ̀run àgbo, tabi si ẹgbẹgbãrun iṣàn òroro? emi o ha fi àkọbi mi fun irekọja mi, iru-ọmọ inu mi fun ẹ̀ṣẹ ọkàn mi?
A ti fi hàn ọ, Iwọ enia, ohun ti o dara; ati ohun ti Oluwa bère lọwọ rẹ, bikoṣe ki o ṣe otitọ, ki o si fẹ ãnu, ati ki o rìn ni irẹ̀lẹ pẹlu Ọlọrun rẹ?

Ẹ gbọ́ nisisiyi ohun ti Oluwa wi; Dide, ba oke nla wijọ, si jẹ ki oke kékèké gbohùn rẹ. Ẹ gbọ́ ẹjọ Oluwa, ẹnyin oke-nla, ati ẹnyin ipilẹ ilẹ̀ aiye: nitori Oluwa mba awọn enia rẹ̀ wijọ, yio si ba Israeli rojọ. Enia mi, kini mo fi ṣe ọ? ati ninu kini mo fi da ọ li agara? dahùn si i. Nitori mo ti mu ọ goke lati ilẹ Egipti wá, mo si rà ọ padà lati ile ẹrú wá; mo si rán Mose, Aaroni, ati Miriamu siwaju rẹ. Enia mi, ranti nisisiyi ohun ti Balaki ọba Moabu gbèro, ati ohun ti Balaamu ọmọ Beori dá a lohùn lati Ṣittimu titi de Gilgali; ki ẹ ba le mọ̀ ododo Oluwa. Kini emi o ha mu wá siwaju Oluwa, ti emi o fi tẹ̀ ara mi ba niwaju Ọlọrun giga? ki emi ha wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọrẹ-ẹbọ sisun, pẹlu ọmọ malu ọlọdún kan? Inu Oluwa yio ha dùn si ẹgbẹgbẹ̀run àgbo, tabi si ẹgbẹgbãrun iṣàn òroro? emi o ha fi àkọbi mi fun irekọja mi, iru-ọmọ inu mi fun ẹ̀ṣẹ ọkàn mi? A ti fi hàn ọ, Iwọ enia, ohun ti o dara; ati ohun ti Oluwa bère lọwọ rẹ, bikoṣe ki o ṣe otitọ, ki o si fẹ ãnu, ati ki o rìn ni irẹ̀lẹ pẹlu Ọlọrun rẹ?

Mik 6:1-8

Micah 6:1-8
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò