Mattheüs 27:50-53

Jesu si tún kigbe li ohùn rara, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ. Si wo o, aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ; ilẹ si mì titi, awọn apata si sán; Awọn isà okú si ṣí silẹ; ọ̀pọ okú awọn ẹni mimọ́ ti o ti sùn si jinde, Nwọn ti inu isà okú wọn jade lẹhin ajinde rẹ̀, nwọn si wá si ilu mimọ́, nwọn si farahàn ọ̀pọlọpọ enia.
Mat 27:50-53