Matthew 25:31-33

Nigbati Ọmọ-enia yio wá ninu ogo rẹ̀, ati gbogbo awọn angẹli mimọ́ pẹlu rẹ̀, nigbana ni yio joko lori itẹ́ ogo rẹ̀: Niwaju rẹ̀ li a o si kó gbogbo orilẹ ède jọ: yio si yà wọn si ọ̀tọ kuro ninu ara wọn gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti iyà agutan rẹ̀ kuro ninu ewurẹ: On o si fi agutan si ọwọ́ ọtún rẹ̀, ṣugbọn awọn ewurẹ si ọwọ́ òsi.
Mat 25:31-33