Matthew 2:1-4

NIGBATI a si bí Jesu ni Betlehemu ti Judea, nigba aiye Herodu ọba, kiyesi, awọn amoye kan ti ìha ìla-õrùn wá si Jerusalemu, Nwọn mbère wipe, Nibo li ẹniti a bí ti iṣe ọba awọn Ju wà? nitori awa ti ri irawọ rẹ̀ ni ìla-õrùn, awa si wá lati foribalẹ fun u. Nigbati Herodu ọba si gbọ́, ara rẹ̀ kò lelẹ, ati gbogbo awọn ará Jerusalemu pẹlu rẹ̀. Nigbati o si pè gbogbo awọn olori alufa ati awọn akọwe awọn enia jọ, o bi wọn lẽre ibiti a o gbé bí Kristi.
Mat 2:1-4