Lukas 6:27-32

Ṣugbọn mo wi fun ẹnyin ti ngbọ́, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ṣore fun awọn ti o korira nyin. Sure fun awọn ti nfi nyin ré, si gbadura fun awọn ti nkẹgan nyin. Ẹniti o ba si lù ọ ni ẹrẹkẹ kan, pa ekeji dà si i pẹlu; ati ẹniti o gbà agbada rẹ, máṣe da a duro lati gbà àwọtẹlẹ rẹ pẹlu. Si fifun gbogbo ẹniti o tọrọ lọdọ rẹ; lọdọ ẹniti o si kó ọ li ẹrù, má si ṣe pada bère. Gẹgẹ bi ẹnyin si ti fẹ ki enia ki o ṣe si nyin, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ si wọn pẹlu. Njẹ bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nfẹ́ awọn ti o fẹ wọn.
Luk 6:27-32