Luke 24:5-8

Nigbati ẹ̀ru mbà wọn, ti nwọn si dojubolẹ, awọn angẹli na bi wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá alãye lãrin awọn okú? Ko si nihinyi, ṣugbọn o jinde: ẹ ranti bi o ti wi fun nyin nigbati o wà ni Galili, Pe, A ko le ṣaima fi Ọmọ-enia le awọn enia ẹlẹsẹ lọwọ, a o si kàn a mọ agbelebu, ni ijọ kẹta yio si jinde. Nwọn si ranti ọ̀rọ rẹ̀.
Luk 24:5-8