John 3:19-21

Eyi ni idajọ na pe, imọlẹ wá si aiye, awọn enia si fẹ òkunkun jù imọlẹ lọ, nitoriti iṣẹ wọn buru. Nitori olukuluku ẹniti o ba hùwa buburu ni ikorira imọlẹ, ki isi wá si imọlẹ, ki a máṣe ba iṣẹ rẹ̀ wí. Ṣugbọn ẹniti o ba nṣe otitọ ni iwá si imọlẹ, ki iṣẹ rẹ̀ ki o le fi ara hàn pe, a ṣe wọn nipa ti Ọlọrun.
Joh 3:19-21