John 16:8-13

Nigbati on ba si de, yio fi òye yé araiye niti ẹ̀ṣẹ, ati niti ododo, ati niti idajọ: Niti ẹ̀ṣẹ, nitoriti nwọn kò gbà mi gbọ́; Niti ododo, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba, ẹnyin kò si ri mi mọ́; Niti idajọ, nitoriti a ti ṣe idajọ alade aiye yi. Mo ni ohun pipọ lati sọ fun nyin pẹlu, ṣugbọn ẹ kò le gbà wọn nisisiyi. Ṣugbọn nigbati on, ani Ẹmí otitọ ni ba de, yio tọ́ nyin si ọ̀na otitọ gbogbo; nitori kì yio sọ̀ ti ara rẹ̀; ṣugbọn ohunkohun ti o ba gbọ́, on ni yio ma sọ: yio si sọ ohun ti mbọ̀ fun nyin.
Joh 16:8-13