John 14:22-24

Judasi wi fun u pe, (kì iṣe Iskariotu) Oluwa, ẽhatiṣe ti iwọ ó fi ara rẹ hàn fun awa, ti kì yio si ṣe fun araiye? Jesu dahùn o si wi fun u pe, Bi ẹnikan ba fẹràn mi, yio pa ọ̀rọ mi mọ́: Baba mi yio si fẹran rẹ̀, awa o si tọ̀ ọ wá, a o si ṣe ibugbe wa pẹlu rẹ̀. Ẹniti kò fẹràn mi ni ko pa ọ̀rọ mi mọ́: ọ̀rọ ti ẹnyin ngbọ́ kì si iṣe ti emi, ṣugbọn ti Baba ti o rán mi.
Joh 14:22-24