John 14:15-18

Bi ẹnyin ba fẹran mi, ẹ ó pa ofin mi mọ́. Emi ó si bère lọwọ Baba, on ó si fun nyin li Olutunu miran, ki o le mã ba nyin gbé titi lailai, Ani Ẹmí otitọ nì; ẹniti araiye kò le gbà, nitoriti kò ri i, bẹ̃ni kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ẹnyin mọ̀ ọ; nitoriti o mba nyin gbe, yio si wà ninu nyin. Emi kì o fi nyin silẹ li alaini baba: emi ó tọ̀ nyin wá.
Joh 14:15-18