John 10:7-11

Nitorina Jesu tún wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Emi ni ilẹkun awọn agutan. Olè ati ọlọṣà ni gbogbo awọn ti o ti wá ṣiwaju mi: ṣugbọn awọn agutan kò gbọ́ ti wọn. Emi ni ilẹkun: bi ẹnikan ba ba ọdọ mi wọle, on li a o gbà là, yio wọle, yio si jade, yio si ri koriko. Olè kì iwá bikoṣe lati jale, ati lati pa, ati lati parun: emi wá ki nwọn le ni ìye, ani ki nwọn le ni i lọpọlọpọ. Emi ni oluṣọ-agutan rere: oluṣọ-agutan rere fi ẹmí rẹ̀ lelẹ nitori awọn agutan.
Joh 10:7-11