A! Oluwa Ọlọrun! wò o, iwọ ti o da ọrun on aiye nipa agbara nla rẹ ati ninà apa rẹ: kò si ohun-kohun ti o ṣoro fun ọ.
Iwọ ṣe ãnu fun ẹgbẹgbẹrun, o si san aiṣedede awọn baba si aiya awọn ọmọ lẹhin wọn: Ọlọrun titobi, Alagbara! Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.