James 4:2-4

Ẹnyin nfẹ, ẹ kò si ni: ẹnyin npa, ẹ si nṣe ilara, ẹ kò si le ni: ẹnyin njà, ẹnyin si njagun; ẹ ko ni, nitoriti ẹnyin kò bère. Ẹnyin bère, ẹ kò si ri gbà, nitoriti ẹnyin ṣì i bère, ki ẹnyin ki o le lò o fun ifẹkufẹ ara nyin. Ẹnyin panṣaga ọkunrin, ati panṣaga obinrin, ẹ kò mọ̀ pe ìbarẹ́ aiye ìṣọtá Ọlọrun ni? nitorina ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jẹ́ ọrẹ aiye di ọtá Ọlọrun.
Jak 4:2-4