Isaiah 53:2-3

Nitori yio dàgba niwaju rẹ̀ bi ọ̀jẹlẹ ohun ọ̀gbin, ati bi gbòngbo lati inu ilẹ gbigbẹ: irísi rẹ̀ kò dara, bẹ̃ni kò li ẹwà, nigbati a ba si ri i, kò li ẹwà ti a ba fi fẹ ẹ. A kẹgan rẹ̀ a si kọ̀ ọ lọdọ awọn enia, ẹni-ikãnu, ti o si mọ̀ ibanujẹ: o si dabi ẹnipe o mu ki a pa oju wa mọ kuro lara rẹ̀; a kẹgàn rẹ̀, awa kò si kà a si.
Isa 53:2-3