Nitorina o si le gba wọn là pẹlu titi de opin, ẹniti o ba tọ̀ Ọlọrun wá nipasẹ rẹ̀, nitoriti o mbẹ lãye titi lai lati mã bẹ̀bẹ fun wọn.
Nitoripe irú Olori Alufa bẹ̃ li o yẹ wa, mimọ́, ailẹgan, ailẽri, ti a yà si ọ̀tọ kuro ninu ẹlẹṣẹ, ti a si gbéga jù awọn ọrun lọ