Heb 13:15-18

Njẹ nipasẹ rẹ̀, ẹ jẹ ki a mã ru ẹbọ iyìn si Ọlọrun nigbagbogbo, eyini ni eso ète wa, ti njẹwọ orukọ rẹ̀. Ṣugbọn ati mã ṣõre on ati mã pinfunni ẹ máṣe gbagbé: nitori irú ẹbọ wọnni ni inu Ọlọrun dùn si jọjọ. Ẹ mã gbọ ti awọn ti nṣe olori nyin, ki ẹ si mã tẹriba fun wọn: nitori nwọn nṣọ ẹṣọ nitori ọkàn nyin, bi awọn ti yio ṣe iṣíro, ki nwọn ki o le fi ayọ̀ ṣe eyi, li aisi ibinujẹ, nitori eyiyi yio jẹ ailere fun nyin. Ẹ mã gbadura fun wa: nitori awa gbagbọ pe awa ni ẹri-ọkàn rere, a si nfẹ lati mã wà lododo ninu ohun gbogbo.
Heb 13:15-18