Gbogbo ibawi kò dabi ohun ayọ̀ nisisiyi, bikoṣe ibanujẹ; ṣugbọn nikẹhin a so eso alafia fun awọn ti a ti tọ́ nipa rẹ̀, ani eso ododo.
Nitorina ẹ na ọwọ́ ti o rọ, ati ẽkun ailera;
Ki ẹ si ṣe ipa-ọna ti o tọ fun ẹsẹ nyin, ki eyiti o rọ má bã kuro lori iké ṣugbọn ki a kuku wo o san.