Ní atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun ati aiye.
Aiye si wà ni jũju, o si ṣofo; òkunkun si wà loju ibú: Ẹmi Ọlọrun si nràbaba loju omi.
Ọlọrun si wipe, Ki imọlẹ ki o wà: imọlẹ si wà.
Ọlọrun si ri imọlẹ na, pe o dara: Ọlọrun si pàla si agbedemeji imọlẹ ati òkunkun.