Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Genesis 1:1-13

Gẹn 1:1-13 - Ní atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun ati aiye.
Aiye si wà ni jũju, o si ṣofo; òkunkun si wà loju ibú: Ẹmi Ọlọrun si nràbaba loju omi.
Ọlọrun si wipe, Ki imọlẹ ki o wà: imọlẹ si wà.
Ọlọrun si ri imọlẹ na, pe o dara: Ọlọrun si pàla si agbedemeji imọlẹ ati òkunkun.
Ọlọrun si pè imọlẹ ni Ọsán, ati òkunkun ni Oru. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kini.
Ọlọrun si wipe, Ki ofurufu ki o wà li agbedemeji omi, ki o si yà omi kuro lara omi.
Ọlọrun si ṣe ofurufu, o si yà omi ti o wà nisalẹ ofurufu kuro lara omi ti o wà loke ofurufu: o si ri bẹ̃.
Ọlọrun si pè ofurufu ni Ọrun. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ keji.
Ọlọrun si wipe, Ki omi abẹ ọrun ki o wọjọ pọ̀ si ibi kan, ki iyangbẹ ilẹ ki o si hàn: o si ri bẹ̃.
Ọlọrun si pè iyangbẹ ilẹ ni Ilẹ; o si pè iwọjọpọ̀ omi ni Okun: Ọlọrun si ri pe o dara.
Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o hù oko, eweko ti yio ma so eso, ati igi eleso ti yio ma so eso ni irú tirẹ̀, ti o ni irugbin ninu lori ilẹ: o si ri bẹ̃.
Ilẹ si sú koriko jade, eweko ti nso eso ni irú tirẹ̀, ati igi ti nso eso, ti o ni irugbin ninu ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara.
Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹta.

Ní atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun ati aiye. Aiye si wà ni jũju, o si ṣofo; òkunkun si wà loju ibú: Ẹmi Ọlọrun si nràbaba loju omi. Ọlọrun si wipe, Ki imọlẹ ki o wà: imọlẹ si wà. Ọlọrun si ri imọlẹ na, pe o dara: Ọlọrun si pàla si agbedemeji imọlẹ ati òkunkun. Ọlọrun si pè imọlẹ ni Ọsán, ati òkunkun ni Oru. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kini. Ọlọrun si wipe, Ki ofurufu ki o wà li agbedemeji omi, ki o si yà omi kuro lara omi. Ọlọrun si ṣe ofurufu, o si yà omi ti o wà nisalẹ ofurufu kuro lara omi ti o wà loke ofurufu: o si ri bẹ̃. Ọlọrun si pè ofurufu ni Ọrun. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ keji. Ọlọrun si wipe, Ki omi abẹ ọrun ki o wọjọ pọ̀ si ibi kan, ki iyangbẹ ilẹ ki o si hàn: o si ri bẹ̃. Ọlọrun si pè iyangbẹ ilẹ ni Ilẹ; o si pè iwọjọpọ̀ omi ni Okun: Ọlọrun si ri pe o dara. Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o hù oko, eweko ti yio ma so eso, ati igi eleso ti yio ma so eso ni irú tirẹ̀, ti o ni irugbin ninu lori ilẹ: o si ri bẹ̃. Ilẹ si sú koriko jade, eweko ti nso eso ni irú tirẹ̀, ati igi ti nso eso, ti o ni irugbin ninu ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹta.

Gẹn 1:1-13

Genesis 1:1-13
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò