Gal 6:8-10

Nitori ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti ara rẹ̀, nipa ti ara ni yio ká idibajẹ; ṣugbọn ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti Ẹmí, nipa ti Ẹmí ni yio ká ìye ainipẹkun. Ẹ má si jẹ ki agãra da wa ni rere iṣe: nitori awa ó ká nigbati akokò ba de, bi a kò bá ṣe ãrẹ̀. Njẹ bi a ti nri akoko, ẹ jẹ ki a mã ṣore fun gbogbo enia, ati pãpa fun awọn ti iṣe ara ile igbagbọ́.
Gal 6:8-10