Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Gal 6:1-10

Gal 6:1-10 - ARÁ, bi a tilẹ mu enia ninu iṣubu kan, ki ẹnyin ti iṣe ti Ẹmí ki o mu irú ẹni bẹ̃ bọ̀ sipò ni ẹmí iwa tutu; ki iwọ tikararẹ mã kiyesara, ki a má ba dan iwọ nã wò pẹlu.
Ẹ mã rù ẹrù ọmọnikeji nyin, ki ẹ si fi bẹ̃ mu ofin Kristi ṣẹ.
Nitori bi enia kan ba nrò ara rẹ̀ si ẹnikan, nigbati kò jẹ nkan, o ntàn ara rẹ̀ jẹ.
Ṣugbọn ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ ara rẹ̀ wò, nigbana ni yio si ni ohun iṣogo nipa ti ara rẹ̀ nikan, kì yio si ṣe nipa ti ọmọnikeji rẹ̀.
Nitori olukuluku ni yio rù ẹrù ti ara rẹ̀.
Ṣugbọn ki ẹniti a nkọ́ ninu ọ̀rọ na mã pese ohun rere gbogbo fun ẹniti nkọni.
Ki a máṣe tàn nyin jẹ; a kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká.
Nitori ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti ara rẹ̀, nipa ti ara ni yio ká idibajẹ; ṣugbọn ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti Ẹmí, nipa ti Ẹmí ni yio ká ìye ainipẹkun.
Ẹ má si jẹ ki agãra da wa ni rere iṣe: nitori awa ó ká nigbati akokò ba de, bi a kò bá ṣe ãrẹ̀.
Njẹ bi a ti nri akoko, ẹ jẹ ki a mã ṣore fun gbogbo enia, ati pãpa fun awọn ti iṣe ara ile igbagbọ́.

ARÁ, bi a tilẹ mu enia ninu iṣubu kan, ki ẹnyin ti iṣe ti Ẹmí ki o mu irú ẹni bẹ̃ bọ̀ sipò ni ẹmí iwa tutu; ki iwọ tikararẹ mã kiyesara, ki a má ba dan iwọ nã wò pẹlu. Ẹ mã rù ẹrù ọmọnikeji nyin, ki ẹ si fi bẹ̃ mu ofin Kristi ṣẹ. Nitori bi enia kan ba nrò ara rẹ̀ si ẹnikan, nigbati kò jẹ nkan, o ntàn ara rẹ̀ jẹ. Ṣugbọn ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ ara rẹ̀ wò, nigbana ni yio si ni ohun iṣogo nipa ti ara rẹ̀ nikan, kì yio si ṣe nipa ti ọmọnikeji rẹ̀. Nitori olukuluku ni yio rù ẹrù ti ara rẹ̀. Ṣugbọn ki ẹniti a nkọ́ ninu ọ̀rọ na mã pese ohun rere gbogbo fun ẹniti nkọni. Ki a máṣe tàn nyin jẹ; a kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká. Nitori ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti ara rẹ̀, nipa ti ara ni yio ká idibajẹ; ṣugbọn ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti Ẹmí, nipa ti Ẹmí ni yio ká ìye ainipẹkun. Ẹ má si jẹ ki agãra da wa ni rere iṣe: nitori awa ó ká nigbati akokò ba de, bi a kò bá ṣe ãrẹ̀. Njẹ bi a ti nri akoko, ẹ jẹ ki a mã ṣore fun gbogbo enia, ati pãpa fun awọn ti iṣe ara ile igbagbọ́.

Gal 6:1-10

Gal 6:1-10
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò