Exodus 33:13-18

Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, fi ọ̀na rẹ hàn mi nisisiyi, ki emi ki o le mọ̀ ọ, ki emi ki o le ri ore-ọfẹ li oju rẹ: ki o si rò pe orilẹ-ède yi enia rẹ ni. On si wipe, Oju mi yio ma bá ọ lọ, emi o si fun ọ ni isimi. On si wi fun u pe, Bi oju rẹ kò ba bá wa lọ, máṣe mú wa gòke lati ihin lọ. Nipa ewo li a o fi mọ̀ nihinyi pe, emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ani emi ati awọn enia rẹ? ki iha iṣe ni ti pe iwọ mbá wa lọ ni, bẹ̃ni a o si yà wa sọ̀tọ, emi ati awọn enia rẹ, kuro lara gbogbo enia ti o wà lori ilẹ? OLUWA si wi fun Mose pe, Emi o ṣe ohun yi ti iwọ sọ pẹlu: nitoriti iwọ ri ore-ọfẹ li oju mi, emi si mọ̀ ọ li orukọ. O si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ogo rẹ̀ hàn mi.
Eks 33:13-18