Ephesians 4:1-6

NITORINA emi ondè ninu Oluwa, mbẹ̀ nyin pe, ki ẹnyin ki o mã rìn bi o ti yẹ fun ìpe na ti a fi pè nyin, Pẹlu irẹlẹ gbogbo ati inu tutù, pẹlu ipamọra, ẹ mã fi ifẹ farada a fun ẹnikeji nyin; Ki ẹ si mã lakaka lati pa iṣọkan Ẹmí mọ́ ni ìdipọ alafia. Ara kan ni mbẹ, ati Ẹmí kan, ani bi a ti pè nyin sinu ireti kan ti ipè nyin; Oluwa kan, igbagbọ́ kan, baptismu kan, Ọlọrun kan ati Baba gbogbo, ẹniti o wà lori gbogbo ati nipa gbogbo ati ninu nyin gbogbo.
Efe 4:1-6