Ki a ba le fi ọ̀pọlọpọ onirũru ọgbọ́n Ọlọrun hàn nisisiyi fun awọn ijoye ati awọn alagbara ninu awọn ọrun, nipasẹ ijọ,
Gẹgẹ bi ipinnu ataiyebaiye ti o ti pinnu ninu Kristi Jesu Oluwa wa:
Ninu ẹniti awa ni igboiya, ati ọ̀na pẹlu igbẹkẹle nipa igbagbọ́ wa ninu rẹ̀.